Script 1
[A ma lo ọrọ-ori-fonran yi ninu fọnran ọja-tita wa. A fẹ ki ohun rẹ jade daadaa, ki o dun ki o si ja gere]
Kini idi ti a fi jẹ aayo ti o dara julọ lati ni awọn ọlọrọ-ori-fọnran akọṣẹmọṣẹ?
Lakọkọ, ọrọ-ori-fonran wa jẹ eyi ti o dara julọ ti awọn ọmọ-ẹgbẹ Alayẹwo wa ṣe ayẹwo rẹ finni-finni. Ati wipe, ogunlọgọ awọn onsọrọ-ori-fọnran wa ni ẹgbẹgbẹrun ara ọtọ ni ede pupo ati iye owo ti o ba mu! Leke gbogbo rẹ, awọn iṣẹ wa tun wa labẹ Eto Itẹlọrun wa, bi inu yin ko ba dun si esi, Alakoso wa yio da si ni kiakia wọn yio si da owo yin pada. [Da ẹnu duro diẹ lẹhin ọrọ kọọkan]. Ko si ibeere.
A kundun ṣiṣe atọnisọna fun onibara, inu awọn ọmọ-ẹgbẹ wa si dun lati ran yin lọwọ. A fẹ ri daju wipe iriri yin pẹlu wa jẹ eyi ti ko mu wahala dani rara, ti o jẹ ojulowo, [Da ẹnu duro diẹ nibi yii] ti o si da'ni laraya!
Script 2
[This recording will be used in our marketing campaign video. A fẹ ki ohun re ja gere, ki o dun, ki o si dabi abami die.]
Ninu aiye ti o ṣoro diẹ nigbakan ri lati ri ọrọ-ori-fọnran gba. Ninu aiye ti o nira ti o si wọn pupọ nigbakan ri lati ṣe iṣẹ Onsọrọ-ori-fọnran, a pinnu lati bẹrẹ iyipada.
Ko rọrun rara, ṣugbọn okun wa npo si ju ti tẹlẹ lọ.
Ni ṣisẹ-ntẹle, a ti ṣẹda ẹrọ igbalode lati mu ile-iṣẹ ọlọrọ-ori-fọnran wa si ẹnu-ọna ile yin. A ti fi ẹyin na sinu eto yi bakanna beni a nfojusọna lati ri wipe ẹyin na kopa ninu iran yii.
Ao ni boju w'ẹyin.
A de, a yi aiye pada, a si wa nibi sibẹ. [Da ẹnu duro diẹ nibi] lati sọ wipe.
A nmu ile-iṣẹ ọlọrọ-ori-fọnran wa si atẹlẹwọ yin.